Matthew 26:33-35

33Peteru sì dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”

34Jesu wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, ní òru yìí, kí àkùkọ kí ó tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.”

35Peteru wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí.

Copyright information for YorBMYO